There is a growing scholarship that shows how myths, mysteries, common sayings and beliefs aid the advancement of a sustainable future for human and nonhuman species. This article takes one such example, the Yorùbá concepts of Ìgbàgbọ́ and Ìmọ̀, and explores their relevance for contemporary global discourses on sustainability that extend beyond the context of one local community. The article argues that the myths, mysteries, proverbs, common sayings and beliefs circulated about human and nonhuman species within Yorùbá communities (classified as Ìgbàgbọ́) reinforce the relevance of the global agenda for a sustainable future for all. The article shows that the encoded ideas in the Yorùbá myths, mysteries, proverbs and other narrative forms on human and nonhuman species complement the extant philosophical and ecological thoughts in global scholarship. This complementarity speaks to the importance of collaborative efforts for the mitigation of an undesirable future for human and nonhuman species and thus is of relevance for the agenda of a sustainable future grounded in a non-discriminatory global partnership.
Is̩é̩ akadá kan tí ó ń dágbàsókè, tí ó ń s̩e àfihàn ìtàn, ohun ìjìnlè̩, àwo̩n ìso̩ tó wó̩ pò̩ àti ìgbàgbó̩ tó ń s̩e ìrànwó̩ fún ìdàgbàsókè ìdúrósinsin o̩jó̩ iwájú fún ènìyàn àti ohun tí kìí s̩e ènìyàn wa. Àpilè̩ko̩ yìí mú àpe̩e̩re̩ irú rè̩, ìwòye Yorùbá nípa ìgbàgbó̩ àti ìmò̩, ó sì s̩e àyẹ̀wò ìjìnlè̩ nípa bí èyí ṣe bá àjo̩so̩ àkókò bágbàmu ní àgbáyé lórí ìmúdúró sinsin tí ó tàn ko̩já ìjo̩ba ìbílè̩ mu. Àpilè̩ko̩ yìí jé̩ kí ó di mímò̩ pé àwo̩n ìtàn, ohun ìjìnlè̩, òwe, ìpèdè tí ó wó̩pò̩ àti ìgbàgbó̩ tí ó tàn ká láàárín àwùjo̩ Yorùbá nípa è̩dá ènìyàn àti ohun tí kì í s̩e ènìyàn (tí a yà só̩tò̩ gé̩gé̩ bi ìgbàgbó̩) mú agbára wá fún ètò tí ó ní ìtumò̩ ní àgbáyé fún ìmúdúró sinsin o̩jó̩ iwájú ohun gbogbo. Àpilè̩ko̩ yìí fihàn pe ò̩rò̩ alárokò inú ̀itàn Yorùbá, ohun ìjìnlè̩, òwe àti àwo̩n o̩nà alòhun nípa è̩dá ènìyàn àti ohun tí kì í s̩e ènìyàn kó̩wò̩rin pò̩ pè̩lú àwo̩n èrò àwùjo̩ nínú è̩kó̩ àgbáyé. Ìbás̩epò̩ yìí sò̩rò̩ nípa pàtàkì ìfo̩wó̩sowó̩pò̩ fún àtúns̩e ìgbé ayé fún è̩dá ènìyàn àti ohun ti kì í s̩e ènìyàn, èyí sì wà ní ìbámu pè̩lú ètò ìmúdúró sinsin o̩jó̩ iwajú àgbáyé tí kò si e̩lé̩yàmè̩yà.